care

Li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa. Nigbati ẹnyin ba pejọ, ati ẹmí mi, pẹlu agbara Jesu Kristi Oluwa wa,

KỌRINTI KINNI 5 : 4

Nigbati o si wọle, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi npariwo, ti ẹ si nsọkun? ọmọ na ko kú, ṣugbọn sisùn li o sùn.

MAKU 5 : 39

Nitorina gẹgẹbi Ẹmí Mimọ́ ti wi, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,

HEBERU 3 : 7

Emi njowere; ori mi tẹ̀ ba gidigidi; emi nṣọ̀fọ kiri li gbogbo ọjọ.

ORIN DAFIDI 38 : 6

MATIU 28 : 56

Njẹ bi gbogbo ara rẹ ba kun fun imọlẹ, ti ko li apakan ti o ṣokunkun, ara rẹ, gbogbo ni yio kun fun imọlẹ, bi igbati fitila ba fi itanṣan rẹ̀ fun ọ ni imọlẹ.

LUKU 11 : 36

Nigbati Jesu si de ibẹ̀, o gbé oju soke, o si ri i, o si wi fun u pe, Sakeu, yara, ki o si sọkalẹ; nitori emi kò le ṣaiwọ ni ile rẹ loni.

LUKU 19 : 5

Ki ẹnyin ki o kuku mã ṣe itọrẹ ãnu ninu ohun ti ẹnyin ni; si kiyesi i, ohun gbogbo li o di mimọ́ fun nyin.

LUKU 11 : 41

Ẹ fi ogo fun orukọ Oluwa: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá si agbala rẹ̀.

ORIN DAFIDI 96 : 8

Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, kó ẹbọ sisun nyin pẹlu ẹbọ jijẹ nyin, ki ẹ si jẹ ẹran.

JEREMAYA 7 : 21